Nípa
Ìwé mímọ awọn onígbàgbọ ba wa sọrọ lapapọ pẹlu itan ati isọtẹlẹ. O sọ fun wa nipa awọn ohun ti wọn ti wa ṣaaju ati eyi ti o n bọ laipẹ. Ninu asọtẹlẹ kan ti o banilẹru, a le ka iṣẹ iranṣẹ ẹ ti ikilọ ikẹyin ṣaaju iparun aye.
Iṣẹ iranṣẹ ikilọ yi i, tí awọn Angẹli Mẹta inu Ifihan 14 ṣ'alaye rẹ, wá ni ipele mẹta. O ṣe pataki ki gbogbo aye gbọ awọn ikilọ wọnyi.
Angẹli akọkọ sọ fun wa wi pe ki a jọsin si Ọlọrun Ẹlẹda a, Ẹni ti o da ọrun, aye ati okun. A gbọdọ sin Ẹlẹda a nitori pe wakati idajọ Rẹ ti de. Angẹli akọkọ sọ fun wa bi a ṣe le mọ Ọlọrun yi i, ati bi a ṣe le mura silẹ lati la idajọ kọja.
Angẹli keji kì wá nilọ nipa iyapa ẹsin ni akoko ikẹyin. A sọ fun wa lati jade kuro ninu awọn ilana ẹsin ti ko bu ọla fun Ọlọrun Ẹlẹda a ati Ọrọ Rẹ ti a fihan.
Angẹli kẹta kì wá nílọ̀ wi pe ẹni buburu u naa yo o ṣiṣẹ nipasẹ ilana ẹsin ti o ti yapa kuro ninu ẹkọ lati ṣe ikolu kan ti o kẹyin si Ọlọrun Ẹlẹda a ati awọn eniyan Rẹ. Àmì' kan wa ti won yoo fi si ori awọn ti wọn n tẹle ẹni buburu na a, ao si ṣe inunibini si awọn ti wọn jẹ olootọ si Ọlọrun sibe. Ṣugbọn Ọlọrun yo o tú ìdájọ́ Rẹ sí orí awọn ti wọn ni àmì buburu yi i. Awọn eniyan Rẹ, ti wọn ni igbagbọ ti wọn si gbọran, ni a o gbala kuro ninu iparun aye ti o n ku lọ. Wọn yo o lọ si ọrun pẹlu Ọlọrun, wọn yo o si ri bi O ti n ṣe àtúndá aye si ipo pípé ti o wà ni ibẹrẹ.
Fi orúkọ sílẹ̀ fun awọn ìwé-ìròyìn wa
Jẹ́ ẹni akọkọ ti yo o mọ igba ti awọn atẹjade tuntun bá ti jade!
Wá Àwọn Olugbọ ọ Rẹ
Awọn atẹjade ti o fi ara han
© 2024 Sharing Hope Publications