
Bi O ṣe le Ronu Fun Ara Rẹ
Akotan
Woli i Ọlọrun sọtẹlẹ nipa agbara ẹsin ti o buru kan eyi ti a pe orukọ idamo rẹ ni "Babiloni." Gẹgẹ bi asọtẹlẹ ti sọ, agbara yi i yo o gbiyanju lati fi ipa mu wa ati lati tan wa jẹ sinu ijọsin èké. Ọna kan ṣoṣo ti a fi le ri aabo ni nipa rironu fun ara wa ki a si ṣe igbọran pipe si Ọrọ Ọlọrun ti a fihan. Iwe-ilewọ yi i sọ fun wa bi a ti ṣe le lo ọpọlọ wa ki a ba a le jẹ onigbagbọ ti o jẹ ọlọgbọn, ti o si n da inú rò ni awọn akoko rogbodiyan-an kariaye.
Tẹ̀
Tract
Òǹtẹ̀wé
Sharing Hope Publications
A le è ri ní
21 Àwọn èdè
Àwọn Ojú-ewé
6
A ṣẹṣẹ de sonso ori-oke Gunung Datuk ni lẹyin ti a ti rin fun igba pipẹ. Mo joko pẹlu ọrẹ mi tuntun, Adzak, lati jẹgbadun ìrísí àyíká naa. Laipẹ pupọ, ijiroro wa lọ sori ọrọ ẹsin.
Adzak sọ pe, “Emi jẹ ẹni ti o maa n da ronu. Emi ni awọn iwoye ti ara mi nipa aye.”
“A a bẹẹni,” Mo fèsì. “Emi ti gbọ́ wipe ọpọlọpọ awọn ọ̀dọ́ ọmọ ilu Malaysia ni wọn n sọ wipe awọn n da ronu.”
Adzak rẹrin-in. “A gbọdọ ronu funra wa. Idarudapọ wa kaakiri. O le dani lori ru.”
“Ṣugbọn nigba ti o ba lọ si ile n kọ?” Mo beere. “Nibi ni Malaysia, ọpọlọpọ awọn ọdọ ni wọn n sọ pe awọn n da ronu funra awọn, ṣugbọn nile, wọn n reti ki o kopa ninu isin Musulumi tabi ijọsin Buddha. Kini o ma a sọ fun awọn obi i rẹ?”
Adzak fesi pe, “Emi ko sọ fun wọn. Ṣugbọn emi kan n ṣe ohun ti wọn n fẹ ni. Emi le ronu ni bi o ti ṣe wu mi, ṣugbọn emi gbọdọ pa a mọ sinu ọkan mi.”
N jẹ Dida Ronu Ṣe Pataki?
Ni awọn apa ibikan ni agbaye, nini awọn igbagbọ ti ko tọna le fa a ki a le ọ kuro ni ilu, ki a le ọ kuro ni ẹnu iṣẹ, tabi ki a pa ọ paapa. Dida ronu funra rẹ le jẹ ohun ti o léwu. Ṣugbọn n jẹ o ṣe pataki?
Aye wa kun fun awọn ero rere ati awọn ero buburu. Ọna kan pataki ti a fi le ya rere kuro ninu ibi ni ki a ronu ki a si sọrọ nipa wọn. Bi iwọ ba ra ohun kan ti o lowo lori—bi i wura, tabi saffron, tabi iPhone—o kò ni dede san owo fun ki o si ma a mu lọ si ile. Wa a yẹ ẹ wo, wa a si ṣe ayẹwo rẹ pẹlu eyi ti awọn ile-iṣẹ miiran ṣe lati le ni idaniloju pe o ra ohun ti o dara julọ. Bakan naa ni a gbọdọ ṣe si ero inu ọkan.
Idarudapọ pọ ninu aye, o si tun n buru si nigba ti awọn eniyan ba n gbiyanju lati fi ipa gbe ero rudurudu wọn le ori awọn eniyan. Jẹ ki n sọ fun ọ nipa asọtẹlẹ pataki kan. Ninu iwe atijọ kan ti a n pe ni “Ifihan Jesu Kristi,” asọtẹlẹ kan sọ nipa awọn eniyan ti wọn n gbiyanju lati fi ipa mu awọn eniyan yoku lati tẹle ero rudurudu ti wọ́n ní nipa ẹsin. O sọ pe, “Bábílónì wó, Bábílónì tí ó tóbi ni wó, èyí tí ó ti n mú gbogbo orilẹ-ede mu nínú ọtí-wáìnì ìbínú àgbèrè rẹ.” (Ìfihàn 14:8)
Awọn ọrọ akajuwe wọnyi ko nira lati yeni. Babiloni jẹ ilu atijọ ti o lokiki, ṣugbọn orukọ rẹ tumọ si “rudurudu.” Ilu yii ti “ṣubu,” ki i ṣe nitori pe rudurudu de ba ṣugbọn nitori pe ko fẹ fi rudurudu rẹ silẹ. O n tan awọn orilẹ-ede jẹ lati darapọ mọ ọ ninu agbere ẹmi ti o n ṣe—eyi ni, dídalẹ̀ Ọlọrun nipa dída ijọsin èké pọ̀ mọ́ ijọsin tootọ. Awọn ero èké wọnyi ni a ri bi ohun ti o tọna ti a si tẹwọgba. Isọtẹlẹ yii nipa “Babiloni” tọka si ilana ẹmi ti o kari aye kan ti yoo jẹ ki a ri aṣiṣe ti ẹmi bi ohun ti o dara, ti yoo si gbiyanju lati fi ipa mu awọn eniyan ti wọn dirọ mọ otitọ lati tẹle.
Ifihan Jesu Kristi sọtẹlẹ pe eyi yoo ṣẹlẹ ni akoko wa. Boya iwọ ti ri eyi ti o n ṣẹlẹ. N jẹ awọn eniyan wà ti wọn fi Ọlọrun han pẹlu ero eke bi? Njẹ ẹri ọkan rẹ n yọ ọ́ lẹnu bi? Bẹẹni, idi niyi ti dídá inú rò fi ṣe pataki.
Bi O ṣe le Ronu Fun Ara Rẹ
Ọpọ awọn eniyan ni o tẹ lọrun lati tẹle ẹsin ibilẹ wọn. Wọn ko ronu jinlẹ nipa awọn ohun ti wọn gbagbọ. Wọn n tẹle àṣà ẹ̀sin ti ko nitumọ tabi ti wọn ṣeni ni ijamba ju ire lọ. Nigba miran, ani awọn adari ẹsin, ti o yẹ ki wọn o fi ọna ti o lọ si ọdọ Ọlọrun han wa, awọn pẹlu kun fun iwa-ibajẹ.
Bawo ni a ṣe le ṣe awari otitọ? Mo daba pe ki a gbẹkẹle awọn woli. Kini idi? Awọn idi mẹta wa:
Awọn woli ṣe afihan imọ ti o yanilẹnu nipa ọjọ iwaju. Woli Daniẹli sọtẹlẹ nipa bi Europe yoo ti ṣe dide de ipo ti yoo fi jẹgaba lori aye. Jesu Kristi (ti a tun mọ si Isa al-Masih) sọtẹlẹ nipa iparun Jerusalẹmu ni 70 CE. Woli Mose (Musa) sọtẹlẹ nipa itan Ishmaẹli titi di opin akoko.
Awọn woli ṣe afihan imọ ti o yanilẹnu nipa ilera. Woli Mose, ẹni ti o gbe ni bi 3,500 ọdun sẹyin, ṣe alaye nipa jijẹki alaisan o danikan wa, bi a ṣe le da idọti nu ni ọna ti o ba imọtoto mu, ati ilana nipa ṣiṣe afọmọ awọn kokoro ti a ko le fi oju ri. O pin awọn ẹranko ti a da si eyi ti o mọ́ ati aláìmọ́. O tun sọ fun wa lati maṣe jẹ ẹ̀jẹ̀ tabi ọ̀ra nigba ti a ba n jẹ ẹran ti o mọ́. Ani loni paapaa, awọn ti wọn tẹle ilana ounjẹ ati imọtoto rẹ n gbe pẹ fun ọdun mẹẹdogun ju awọn eniyan iyoku lọ.
Ọlọrun n dahun adura awọn onigbagbọ ti wọn gbẹkẹle E ti wọn si gbagbọ ninu awọn woli Rẹ.
Awọn iwe awọn woli kun fun itọsọna—ṣugbọn lati le jeere wọn, a gbọdọ kọ lati ronu ni ọna ti o jinlẹ, lati dan awọn igbagbọ wa wo, ati lati ṣe ayẹwo ẹri fun igbagbọ wa. Ironu jẹ abala ti o ṣe pataki ninu ẹsin tootọ.
Kini yoo ṣẹlẹ nigba ti a ba ṣe ayẹwo èké? O le dabi otitọ ni ibẹrẹ. Ṣugbọn ni bi a ba ṣe n wa ẹri, a yoo maa ri ohun ti ko tọna pẹlu ero naa.
Otitọ ni idakeji rẹ, kii padanu ohunkohun nigba ti a ba ṣe ayẹwo rẹ finifini. Bi a ba ti ṣe n ṣe iwadi rẹ to, bẹẹ ni otitọ ti a o ri yoo maa pọ si.
Awọn onigbagbọ ni o yẹ ki o jẹ ọlọgbọn julọ ninu aye nitori pe Ọlọrun n dari wa ni ọna ọgbọn. Bi iwọ bá ba ara rẹ ni ipo ti a ko ti gba ọ laaye lati ronu pẹlu ominira tabi lati beere ibeere, eyi ko wa lati ọdọ Ọlọrun. Ọlọrun pe wa lati ṣe àyẹ̀wò finifini nitori pe òtítọ́ ní agbára ti o tó lati farada àyẹ̀wò. Ṣugbọn Babiloni n tan ọ jẹ sinu ẹtan, ti yoo si jẹki o duro nibẹ nipa titi ilẹkun mọ akitiyan lati ronu.
Bi iwọ ba wa ninu iporuuru to bẹẹ gẹẹ ti iwọ fi ro pe iwọ wa ninu Babiloni, jade sita! Wa si ọna ọgbọn ti Ọlọrun. Ronu funra rẹ ki o si beere awọn ibeere ti wọn nira. Iwọ ki yoo ri ijakulẹ.
Njẹ iwọ fẹ mọ si nipa Ifihan Jesu Kristi? Jọwọ kan si wa ni adirẹsi ti o wa ni ẹyin iwe yii.
A mu ẹsẹ Bibeli lati inu Bibeli Mimọ Alakọle. Copyright © 2012 lati ọwọ The Bible Society of Nigeria. A lo o pẹlu aṣẹ. A ni aṣẹ lori gbogbo iwe yii.
Fi orúkọ sílẹ̀ fun awọn ìwé-ìròyìn wa
Jẹ́ ẹni akọkọ ti yo o mọ igba ti awọn atẹjade tuntun bá ti jade!

Wá Àwọn Olugbọ ọ Rẹ
Awọn atẹjade ti o fi ara han
© 2024 Sharing Hope Publications