N jẹ Iwọ Nilo Iṣẹ-iyanu bi?

N jẹ Iwọ Nilo Iṣẹ-iyanu bi?

Akotan

Itan pọ̀ nipa bi Ọlọrun ti ṣe ma a n ṣe iṣẹ iyanu fun awọn eniyan Rẹ nigba ti wọn ba nilo wọn julọ. Bibeli sọ awọn itan pupọ fun wa nipa awọn asọtẹlẹ ti wọn wa si imuṣẹ, awọn eniyan ti a wosan, ati awọn iṣẹlẹ agbayanu ti o jẹ wi pe nitori pe wọn jẹ idahun si adura nikan ni wọn fi le ṣẹlẹ. Iwe-ilewọ yi i fun wa ni idi pupọ ti a fi le gbagbọ ninu Bibeli gẹgẹ bi ọrọ Ọlọrun ti ko yipada, ati bi iwọ ṣe le tọ Ọlọrun lọ fun iṣẹ iyanu ti ara rẹ.

Tẹ̀

Tract

Òǹtẹ̀wé

Sharing Hope Publications

A le è ri ní

21 Àwọn èdè

Àwọn Ojú-ewé

6

Danloodu

Awọn ọmọ idile nla kan n reti igbesi aye ti o dara si, wọn si pinu lati lọ maa gbe ni orilẹ-ede titun kan. Irin-ajo naa ko rọrun, wọn nilo lati fi ẹsẹ rin gba aṣálẹ̀ nla kan kọja. Ejo, akeeke, ati ooru gbigbona wa nibẹ. Bi ẹnikẹni ninu awọn idile naa ba kaarẹ tabi ti o ba ṣaisan, ti o wa fa sẹyin, awọn jàndùkú yoo kọlu u.

Laipẹ ounjẹ wọn tan, ṣugbọn adari wọn kigbe si Ọlọrun fun iṣẹ-iyanu. Ni ọjọ keji, nigba ti awọn eniyan naa jí, wọn ri awọn ohun kekeeke kan ti wọn dabi burẹdi ti wọn fọn kaakiri lori ilẹ. O dun lẹnu, o dabi akara fẹlẹfẹlẹ ti a fi oyin ṣe. O si to fun gbogbo wọn lati tẹ ebi ti n pa wọn lọrun! O gba wọn ni ọjọ pipẹ lati la aṣálẹ̀ naa kọja, ojoojumọ si ni akara naa n sọkalẹ wa lati ọrun. Ogo ni fun Ọlọrun, wọn ri idande!

Itan yii le yanilẹnu, ṣugbọn o ṣẹlẹ nitootọ. O jẹ ọkan lara awọn ọpọlọpọ iṣẹ-iyanu ti a sọ ninu Bibeli, eyi ti iwọ le mọ orukọ wọn si Tawrat, Zabur, ati Injeel. Bibeli kun fun ọpọlọpọ itan ti wọn jẹ otitọ, ọpọ ninu wọn si ni wọn da lori awọn iṣẹ-iyanu ti Ọlọrun ṣe ninu igbesi aye awọn eniyan. O jẹ iwe pataki fun akoko wa, nigba ti ọpọlọpọ awọn eniyan nilo iṣẹ-iyanu ti ara wọn.

Awọn Iṣẹ-iyanu Ode Oni

Ni aipẹ yii, a ti ri ogun abẹle, idoju ijọba bolẹ, iṣubu eto ọrọ̀-ajé, àìníṣẹ́, awọn ajakalẹ arun, ati iku. Emi ko mọ iru ipo ti iwọ wa ni akoko yii. A ti le ṣi ọ nidi kuro ninu ile rẹ. O le ṣe e ṣe ki o ni olufẹ kan ti o wa ni agbedemeji iye ati iku. O le maa jijadu lati ri iṣẹ.

Ipokipo yoowu ki o wa, Ọlọrun n ṣe itọju rẹ O si fẹ lati ṣe iṣẹ iyanu fun ọ loni gẹgẹ bi O ti ṣe ni igba atijọ. Nigba ti inu rẹ ba bajẹ, o le ri ìmóríyá nipa kika Bibeli, iwe nipa awọn iṣẹ-iyanu.

Ọrọ Ọlọrun fun Akoko wa

Awọn eniyan kan n lọra lati ka Bibeli nitori pe wọn ti gbọ wipe a ti yi pada ni ọna kan. O ṣeeṣe ki ero yii o waye nitori igbesi aye ọpọ awọn ti wọn sọ wipe awọn n tẹle Bibeli. Ni igba miran, a maa n ri awọn Kristẹni ti wọn n mu ọti, ti wọn n ta tẹ́tẹ́, ti wọn n wọ aṣọ ti ko bojumu, ti wọn n jẹ ẹran ẹlẹdẹ, ti wọn si n wuwa ailaanu si awọn eniyan.

Ṣugbọn nitootọ, gbogbo awọn aṣiṣe wọnyi ni Bibeli ko faaye gba. Nigba ti awọn Kristẹni ba n gbe igbe aye aigbọran si Ọlọrun, eyi ko yí bí Ọrọ ayeraye Rẹ ti ṣe jẹ́ otitọ pada. Woli Aisaya kọwe, “Koriko nrọ, itanna n rẹ, ṣugbọn ọrọ Ọlọrun yoo duro titi lailai” (Aisaya 40:8). Njẹ o ro pe awọn eniyan ni agbara lati yi Ọrọ Ọlọrun pada bi, tabi pe wọn tilẹ n ṣe afihan rẹ ni ọna aitọ pẹlu iwa buburu lasan ni? 

Bibeli sọ nipa akoko woli Dafidi (ti a tun mọ si Dawud) nigba ti awọn eniyan rẹ n gbe apoti ẹri kọja lọ, a gbe Ofin Mẹwa sinu apoti nla oniwura naa. Ofin Mẹwa jẹ ofin Ọlọrun fun iwuwasi, a kọ wọn si ori walaa okuta nla meji, ti a si gbe wọn sinu apoti wura naa. Nigba ti wọn n wọde lọ, ọkunrin kan da a laṣa lati na ọwọ rẹ o si fi kan apoti ẹri naa—o si ku lẹsẹkẹsẹ! 

Bi Ọlọrun ko ba gba ki ọwọ ikugbu o kan apoti mimọ ti ọrọ Rẹ wa ninu rẹ, bawo ni yoo ṣe wa gba awọn eniyan buburu laaye lati sunmọ Ọrọ Rẹ ti a kọ silẹ pẹlu ọ̀bẹ ati gègé ti n ṣe atunṣe? Ọlọrun tobi pupọ lati daabo bo Ọrọ Rẹ. 

Bi a ba wo o nitootọ, Bibeli ni iwe ti a ṣe ayẹwo rẹ julọ ninu iwe itan eniyan. Laipẹ yii, awọn darandaran ara Bedouin mẹta kan ni Palẹstin—Muhammad edh-Dhib, Juma Muhammad ati Khalil Musa—ṣe awari Awọn Iwe Ibi Okun Oku lairotẹlẹ. Eyi jẹ awari ti o ṣe gbòógì eyi ti o fun wa ni anfani lati fi Bibeli ti ode oni wé awọn akọsilẹ Bibeli ti igba atijọ ti wọn ti wa fun bi 2,000 ọdun sẹyin. Bí wọn ti ṣe jọ ara wọn yanilẹnu, lẹẹkansi eyi tọka si pe ifihan Ọlọrun ko le yi pada. Bi iwọ ba nilo iṣẹ-iyanu, o le ni idaniloju pe Bibeli jẹ ibi ti o daju ti iwọ ti le ri i! Nibi iwọ yoo ri awọn itan agbayanu nipa awọn woli bi Noah (Nuh), Abrahamu (Ibrahimu), Josẹfu (Yusef), Jonah (Yunus), Daniẹli, Dafidi (Dawud), ati Solomoni (Suleiman). O ti le gbọ́ nipa wọn lerefe ni awọn ibomiran, ṣugbọn Bibeli ni o sọ gbogbo itan naa!

Wa ṣe Awari Iṣẹ-iyanu ti ara Rẹ

Iru wahala yowu ki o maa la kọja, Bibeli ní itan iṣẹ-iyanu fun iwọ nikan:

  • Njẹ iwọ tabi ẹni ti iwọ fẹran n ṣaisan bi? Ka nipa bi a ti ṣe wo Namani ọgagun ara Siria ti o dẹtẹ san ni ọna iyanu. 

  • Njẹ iwọ n tiraka lati wa ounjẹ fun idile rẹ bi? Ka nipa opó ara Lẹbanoni pẹlu ọmọkunrin rẹ, ti o lo gbogbo akoko ìyàn ọlọjọ gbọọrọ pẹlu kólòbó òróró kekere kan ati ìyẹ̀fun kekere kan tí kò tán. 

  • N jẹ ẹmi rẹ wa ninu ewu bi? Ka nipa Ebed-Melech, ara Ethiopia ti o jẹ ẹru ni aafin ọba, ẹni ti a gba ẹmi rẹ la ni igba ogun nitori igbagbọ rẹ ninu Ọlọrun. 

  • Njẹ iwọ n ri ara rẹ bi ẹni ti a tanù bi? Ka nipa Hagari ara Ejipti, ẹni ti o ri awọn iṣẹ-iyanu Ọlọrun nigba ti a kọ ọ silẹ.

  • Njẹ iwọ n tẹri ni abẹ awọn idamu aye bi? Ka nipa akoko ti Jesu Kristi na ọwọ rẹ ti o si da ìjì nla duro lati gba awọn ọmọ-ẹyin rẹ la kuro ninu ijamba ọkọ̀ rírì.

Awọn Idahun Agbayanu

Bi a ti n ka Bibeli, a n kun fun igboya lati gbadura pẹlu ireti ti o dara. Jesu Kristi wi pe, “Ohunkohun ti ẹyin ba beere ninu adura, pẹlu igbagbọ, ẹyin yoo ri gba” (Mattiu 21:22). Nigba ti a ba ka itan awọn miran ti wọn gba iṣẹ-iyanu lọdọ Oluwa, yoo fun ọkan wa lokun pẹlu ireti lati dari ẹbẹ wa lọ si ọrun.

N jẹ iwọ nilo iṣẹ-iyanu bi? Ni imoriya nipasẹ awọn iṣẹ-iyanu inu Bibeli ki o si beere fun ti ara rẹ lọwọ Ọlọrun. Dajudaju yoo gbọ adura rẹ loni!

Bi iwọ ba fẹ mọ si nipa awọn iṣẹ-iyanu ninu Bibeli, jọwọ kan si wa ni adirẹsi ti o wa ni ẹyin iwe yii.

Copyright © 2023 by Sharing Hope Publications. A le tẹ iwe yii jade ki a si pin kaakiri laifi ṣowo lai gba aṣẹ.
A mu ẹsẹ Bibeli lati inu Bibeli Mimọ Alakọle. Copyright © 2012 lati ọwọ The Bible Society of Nigeria. A lo o pẹlu aṣẹ. A ni aṣẹ lori gbogbo iwe yii.

Fi orúkọ sílẹ̀ fun awọn ìwé-ìròyìn wa

Jẹ́ ẹni akọkọ ti yo o mọ igba ti awọn atẹjade tuntun bá ti jade!

newsletter-cover