Ìsinmi Ninu Aye Hílàhílo

Ìsinmi Ninu Aye Hílàhílo

Akotan

Wahala ati iṣẹ aṣeju ma a n jẹ ki ọpọlọpọ awọn eniyan ku ṣaaju akoko o wọn. Ṣugbọn ni igba a dida aye Ọlọrun pese ọna abayọ fun iṣoro wahala: ọjọ isinmi kan. A gbe ọjọ mimọ yi i kalẹ lati jẹ ibukun ki awọn eniyan ba a le sinmi kuro ninu iṣẹ wọn, ki wọn si lo akoko pẹlu Ọlọrun. O ṣeni laanu wi pe, bi o tilẹ jẹ pe Ọlọrun paṣẹ fun awọn eniyan lati ranti rẹ, ọpọ ni wọn ti gbagbe nipa ọjọ pataki yi i, ọpọ ni wọn tun gbagbe Ẹlẹda a ti O fifun wọn.

Tẹ̀

Tract

Òǹtẹ̀wé

Sharing Hope Publications

A le è ri ní

21 Àwọn èdè

Àwọn Ojú-ewé

6

Danloodu

Mita Duran ti kú. Ọ̀dọ́mọbìnrin tẹwetẹwe ọmọ-ọdun mẹ́rìnlelogun ara ilu Indonesia kan ṣubu ni ibi ijoko rẹ. Kilo ṣẹlẹ? 

Mita n ṣiṣẹ nile iṣẹ ipolowo-ọja kan, nibi ti afojusun ti ga pupọ, ti ẹru iṣẹ naa si wuwo. Ki o to di pe o kú, o sọ nipa ikaarẹ rẹ lori ẹrọ ayelujara: “Àṣálẹ́ oni ni o di ọjọ kẹjọ gbáko ti mo ti mú kọkọrọ ibi iṣẹ mi lọwọ. . . . Emi ko ni igbesi aye.”

O gbẹkẹle coffee ti orukọ rẹ n jẹ Krating Daeng, eyi ti o dabi ohun mimu Red Bull ti ile Asia. Ohun ti o sọ kẹyin lori ẹrọ ayelujara ni pe, “mo ti n ṣiṣẹ fun ọgbọn wakati, aarẹ ko si mu mi.” Lẹyin naa ni o ṣubu ni ibi ijoko rẹ ti ko si ji mọ.

Kilo ṣẹlẹ? Mita ku nitori iṣẹ aṣeju.

Loni, ọpọlọpọ wa ni a ni iṣẹ pupọ lati ṣe. Awujọ n tì wá lati ṣe iṣẹ pupọ si, ki a gba owo ti o pọ si, ki a sì ra awọn ohun pupọ si. A n jiya nitori àárẹ̀, àìrórunsùn, ati lílo ọpọlọ ni àlòjù. 

A le ma pa ara wa bi Mita Duran, ṣugbọn igbesi-aye le jẹ ẹru wuwo. Njẹ eyi ni ohun ti Ọlọrun fẹ fun wa bi? Oun ni Ẹni ti n funni ni Alaafia. Nigba ti a ba ṣiṣẹ ju bi o ti yẹ lọ, n jẹ a maa n ni alaafia bi? Rara o!

Nigba ti aarẹ ba bo wa mọlẹ, o gbọdọ jẹ pe a gbagbe ohun kan ti Ọlọrun fẹ ki a ranti ni. Ẹ jẹ ki a ṣe awari ohun ti O sọ nipa isinmi.

Titẹ Bọtini “Idawọduro Diẹ”

Ọlọrun jẹ Oloore-ọfẹ ati Alaanu julọ. O mọ wipe eniyan nilo akoko lati tun ara, ọpọlọ ati agbara ẹmi wọn ṣe, gẹgẹ bi ẹrọ ibanisọrọ alagbeka tabi ẹrọ itẹwe kọmputa. Nitori naa, woli Mose (ti a tun mọ si Musa) ṣe akọsilẹ aṣẹ Ọlọrun:

Ranti ọjọ Isinmi lati ya a si mimọ. Ọjọ mẹfa ni iwọ yoo ṣiṣẹ, ti iwọ yoo si ṣe iṣẹ rẹ gbogbo, ṣugbọn ọjọ keje ni ọjọ Isinmi Oluwa Ọlọrun rẹ. Ninu rẹ, iwọ ko gbọdọ ṣe iṣẹkiṣẹ kan (lati ara abala akọkọ iwe inu Bibeli ti a mọ si Tawrat: Ẹksodu 20:8–10).

Ofin Ọlọrun ti ko le yipada yii sọ fun wa lati ranti ọjọ keje. Gẹgẹ bi o ti ṣe wà ninu ọpọlọpọ ede ni aye, ọjọ keje ti a fi jìn fun isinmi yii ni a n pe ni “Sabbath.” Kini idi ti Ọlọrun fi paṣẹ fun wa lati ranti rẹ? Nitori ti O mọ wipe ìgbàgbé jẹ iṣoro lati ibẹrẹ pẹpẹ pẹlu iran eniyan, eyi ti o bẹrẹ lati ọdọ Adamu. A ko gbọdọ gbagbe ofin Ọlọrun, nitori pe bi a ba ṣe n ranti Rẹ ati ofin Rẹ, bẹẹ ni a yoo maa rin ni ọna taara.

Ṣugbọn kini idi ti Isinmi fi ṣe pataki? Ọlọrun sọ fun wa,

Nitori ni ọjọ mẹfa ni Oluwa da ọrun ati aye, okun ati ohun gbogbo ti n bẹ ninu wọn, O si sinmi ni ọjọ keje. Nitori naa Oluwa bukun ọjọ Isinmi, o si ya a si mimọ (Ẹksodu 20: 11).

Ọjọ Isinmi jẹ ohun ìrán-ni-létí pataki pe Ọlọrun ni Ẹlẹda. Awọn eniyan kan ṣe atako pe niwọn igba ti o jẹ pe Ọlọrun ki i kaarẹ, ko nilo lati sinmi ni ọjọ keje. Ṣugbọn Ọlọrun ko sinmi nitori pe O kaarẹ; O dawọ iṣẹ dida duro ni ki O baa le dá akoko mímọ́ kan fun wa lati sinmi.

Ọlọrun ri pe ọjọ isinmi dara fun araye. O da ọjọ keje ni ọjọ Isinmi, eyi ti o tumọ si idaduro ranpẹ tabi iṣiwọ diẹ. Nitori naa, ọjọ keje ọsọọsẹ jẹ ọjọ pataki lati tẹ bọtini “idawọduro diẹ.” A gbọdọ sinmi kuro ninu iṣẹ ati awọn akitiyan ti ki i ṣe mímọ́ fun odidi ọjọ kan lati ranti Rẹ ati lati jọsin Rẹ.

N jẹ ki yoo dun mọ ọ ninu bi ọga rẹ tabi profẹsọ rẹ ba paṣẹ fun ọ lati sinmi diẹ si bí? Ṣugbọn eyi gan-an ni Ọlọrun pa laṣẹ! Ogo ni fun Ọlọrun! O jẹ alaanu nitootọ! 

Pipa Ọjọ Ọlọrun mọ́ ni Mimọ

Ọjọ Isinmi jẹ ọjọ mimọ ti o kari aye fun gbogbo eniyan ninu aye. Awọn onigbagbọ ti wọn gbagbọ ninu Ọlọrun kan ṣoṣo ti o jẹ Ọlọrun ẹlẹda tootọ pa a mọ ṣaaju ki awọn Ju, awọn Kristẹni, awọn Musulumi, awọn atẹle Buddha, tabi awọn ti wọn n ṣe ẹsin Hindu to wa. Nitootọ, a fifun iran eniyan nigba ti a da aye. Adamu ati Efa (ti a tun mọ si Hawwa) pa ọjọ Isinmi mọ, Ọlọrun ko si fun wa ni aṣẹ lati gbagbe ohun ti O sọ fun wa lati ranti. 

O ṣeni laanu wipe a saba maa n gbagbe ọjọ Isinmi. Awọn woli ṣe ikilọ fun awọn ara Ju atijọ pe Ọlọrun yoo mu iparun wa si ori wọn bi wọn ba gbagbe ọjọ Isinmi. Wọn ko ṣe igbọran si ikilọ naa, nitori naa a pa Jerusalẹmu run, a si ko awọn idile wọn lọ si igbekun. Awọn Kristẹni pẹlu gbagbe nipa ọjọ Isinmi nipa yiyi iwani-mimọ rẹ pada si ori ọjọ Aiku ni itako si ofin Ọlọrun. Awọn Musulumi n gbadura ni ọjọ Ẹti ṣugbọn wọn ti gbagbe pe a gbọdọ sinmi ni ọjọ keje lati le wa ni igbọran pipe si Ẹlẹda.

Kilode ti o fi dabi ẹni pe gbogbo aye n gbagbe ọjọ pataki yii? Njẹ idi miran ti o jinlẹ wa fun ìgbàgbé ti o tan kalẹ yii bi?

Jesu, Mesaya naa (ti a tun n pe ni Isa al-Masih) kilọ fun wa nipa agbara kari aye ti Satani (Shaytan) yoo lo lati yi ọkan wa kuro lọdọ Ẹlẹda wa. Ọgọọrọ awọn eniyan ni a yoo tanjẹ lati maa jọsin ni ọjọ isinmi eke. Bi Satani ba le jẹ ki a gbagbe ọjọ Ẹlẹda, o reti pe a yoo gbagbe Ẹlẹda funra Rẹ. Ṣugbọn, nigba ti a ba pa ọjọ Isinmi tootọ mọ, a fi iṣotitọ wa si Ẹlẹda wa han, a si n jẹgbadun ẹbun isinmi, ifọkanbalẹ ati alaafia.

Wiwọ Inu Isinmi Ọlọrun

Woli Mose kọwe pe “Oluwa bukun ọjọ keje” (Jẹnẹsisi 2: 3). Njẹ aarẹ mu ọ bi? Awọn ibukun wa ninu ọjọ Isinmi! 

Mita Duran, atẹwe ara Indonesia naa ku nitori iṣẹ aṣeju—ṣugbọn ko yẹ ki o ri bẹẹ fun ọ. Ọlọrun pe ọ lati sinmi kuro ninu iṣẹ rẹ ni ọsọọsẹ ki o si ni iriri awọn ibukun ọjọ Isinmi.

Bi iwọ ba fẹ lati mọ si nipa bi Ọlọrun ṣe n fun wa ni isinmi, alaafia ati iwosan, jọwọ kan si wa ni adirẹsi ti o wa ni ẹyin iwe yii.

Copyright © 2023 by Sharing Hope Publications. A le tẹ iwe yii jade ki a si pin kaakiri laifi ṣowo lai gba aṣẹ.
A mu ẹsẹ Bibeli lati inu Bibeli Mimọ Alakọle. Copyright © 2012 lati ọwọ The Bible Society of Nigeria. A lo o pẹlu aṣẹ. A ni aṣẹ lori gbogbo iwe yii.

Fi orúkọ sílẹ̀ fun awọn ìwé-ìròyìn wa

Jẹ́ ẹni akọkọ ti yo o mọ igba ti awọn atẹjade tuntun bá ti jade!

newsletter-cover