
Ìpòngbe fún Àánú
Akotan
Bawo ni aanu Ọlọrun ṣe ri? Ṣé O kàn sọ ọ lasan pe, "Mo dariji ọ", tabi O pese ọna miiran lati wẹ akọsilẹ wa ti o tini loju kuro? Iwe-ilewọ yi i sọ itan ibilẹ kan lati ṣèrànwọ́ lati ṣ'alaye itumọ ati idi fun irubọ arọpo. Awọn onkawe yo o ni ireti ni mímọ̀ wi pe a le dari ẹṣẹ wọn jì ki a si mu itiju wọn kuro.
Tẹ̀
Tract
Òǹtẹ̀wé
Sharing Hope Publications
A le è ri ní
21 Àwọn èdè
Àwọn Ojú-ewé
6
Fatima nikan ni o dá wà ní akoko ọdun ileya, ìdánìkànwà rẹ si pọ ju ohun ti o le farada lọ. Bi o ti ṣe dáwà ni oun nikan jẹ afọwọfa ara rẹ, abi bẹẹ kọ?
Fatima ranti bi o ti ṣe fi igbonara ba baba rẹ jiyan nipa ṣiṣe igbeyawo pẹlu Ahmed. Ọdọmọde ni, ìfẹ si ti ko sii lórí. Bawo ni baba rẹ yoo ṣe sọ pe rara? Nigba ti o sálọ lati fẹ Ahmed, baba a rẹ sọ pe ko gbodo pada mọ lailai.
O ro wi pe oun yoo le e farada itiju naa nitori ifẹ ẹ rẹ si Ahmed. Ṣugbọn laipẹ, o ni lati gba pe baba oun tọna. Ahmed ki i se ẹni ti o ro pe oun nifẹ si. O fi i silẹ ó si tẹ̀lé obinrin miiran lọ.
Itiju de ba Fatima. O gbagbọ pe idajọ ti de si oun, ati pe oun n san gbèsè oun ni. O ni oye nipa idajọ daradara. Ṣugbọn ọkan rẹ ti wọna fun aanu to!
Oloore-ọfẹ ati Alaanu Julọ
Bi a ba ṣotitọ, gbogbo wa ni a ti ṣe awọn aṣiṣe kan ti a si ti kọ ọrọ ọgbọ́n silẹ. A ti ṣẹ awọn miran. Awọn miran si ti ṣẹ wa. Awujọ wa kun fun awọn eniyan ti wọn n ṣe aṣiṣe. O si ti nira to lati dariji awọn miran ati ara wa pẹlu!
N jẹ aanu wa fun awọn aṣiṣe wa bi?
Ronu lori iye igba ti iwọ ti ṣe awitunwi gbolohun ọrọ yii “bismillah Al-Rahman Al-Raheem”—“ni orukọ Ọlọrun, Alaanu, Oloore-ọfẹ julọ.” Kini o ṣe pataki tobẹ ẹ nipa aanu?
Boya nitori pe awọn awujọ wa—ati ọkan wa—nilo aanu pupọpupọ ni.
Aanu: Ọna ti o Dara
Ni ọdun diẹ sẹyin, ọkunrin kan ti a n pe ni Abdul-Rahman ba aladugbo kan ti orukọ rẹ n jẹ Kareem ja, o si pa. Idaduro de ba igbesi aye awọn idile meejeeji ninu abule kekere ilẹ Egypt yii. Awọn ara ile Kareem fẹ gbẹsan, nigba ti awọn ara ile Abdul-Rahman n fi ibẹru gbiyanju lati daabo bo o. Abdul-Rahman ko fẹ ki aago igbẹsan yii tẹsiwaju. O beere fun imọran lati ọdọ awọn adari abule naa, wọn si ni ki o ṣe awọn eto kan ti wọn ni i ṣe pẹlu aṣọ ìsìnkú.
Abdul-Rahman ra aṣọ funfun ti a fi n sin oku, o si fi ọbẹ le lori. O lọ pade awọn ara ile Kareem ni aarin-ọja, ti gbogbo abule naa si n woran iṣẹlẹ naa. Abdul-Rahman kunlẹ niwaju Habib, arakunrin ẹni ti o pa naa, o si gbe aṣọ isinku ati ọbẹ naa fun. O bẹbẹ fun aanu ati ibalaja.
Habib gbe ọ̀bẹ naa le ọrun Abdul-Rahman. Awọn adari abule naa mu aguntan kan wa, Habib si gbọdọ ṣe ipinu rẹ: aanu, tabi igbẹsan? Bi o ti gbe ọbẹ naa le ọrun Abdul-Rahman, iwa rẹ fihan pe, “O wà ni ìkáwọ́ mi ni akoko yii. Gbogbo oju ni o n wo iṣẹlẹ yii; gbogbo eniyan ni wọn mọ pe èmi ní ẹ̀tọ́ lati pa ọ ati agbara lati ṣe bẹẹ. Ṣugbọn emi yan aanu ati ibalaja. Emi yoo mu aáwọ̀ ẹ̀jẹ̀ yii wa si opin.”
O yiju kuro lọdọ Abdul-Rahman, o si pa aguntan naa rọpo. Nigba ti ẹranko naa farada imọlara irora, ibinu ati idajọ tan, Habib dimọ Abdul-Rahman. Alaafia pada si aarin awọn idile mejeeji naa.
Bi eniyan ba le wá ọna lati so aanu pọ mọ idajọ, o daju pe Ọlọrun le ṣe bakan naa!
Jesu Mesaya naa: Aanu lati ọdọ Ọlọrun
Nibo ni a ti le kẹkọ nipa aanu Ọlọrun? O rọrun pupọpupọ. O ṣe e ṣe ki iwọ ti gbọ nipa Jesu, Mesaya naa ri (ti a tun mọ si Isa al-Masih), ẹni ti a n pe ni “Aanu” lati ọdọ Ọlọrun. Eyi tumọ si pe kikida aanu ni. Ọna Rẹ—awọn ikọni rẹ ninu awọn Iwe Iyinrere, eyi ti a tun mọ si Injeel—eyi jẹ ọna si idariji ati ibalaja.
Jesu, Mesaya naa, le ṣe iru iṣẹ agbayanu yii nitori pe oun ni ẹnikan ṣoṣo ti Ọlọrun ran ti ko dẹṣẹ rara. Gbogbo awọn woli ati awọn ojiṣẹ mimọ ni wọn nilo idariji fun awọn aṣiṣe wọn, ṣugbọn ti Jesu, Mesaya ko ri bẹẹ. Dipo ki o duro de Ọjọ Idajọ, a gba a soke lọ si ọrun tààrà nitori pe ko ṣe aṣiṣe ri—ani bi o ti wu ki o mọ.
Idi niyi ti a fi n pe e ni Aanu lati ọdọ Ọlọrun. O fun wa ni apẹẹrẹ aanu ti ko labawọn, o si kọ́ wa nipa bi a ti ṣe le gba aanu Ọlọrun.
Bawo ni Jesu, Mesaya naa, ṣe le Ran mi Lọwọ?
A ṣe akọsilẹ rẹ pe Johanu Onitẹbọmi (ẹni ti a tun mọ si Yahya) ri Jesu, Mesaya naa, ni aarin ọpọ eniyan, ni abẹ imisi lati ọdọ Ọlọrun, o kigbe pe, “Wo o! Ọdọ-aguntan Ọlọrun ẹni ti o ko ẹṣẹ araye lọ!” (Iyinrere ti Johanu 1:29). Jesu, Mesaya naa, dabi aguntan ti o la ọna ibalaja silẹ fun Abdul-Rahman.
Idajọ tumọ si ki a fi iya jẹ wa nitori awọn aṣiṣe wa. Ṣugbọn Jesu, Mesaya naa, ẹni ti ko dẹṣẹ ri, fi ara rẹ silẹ lati gba ojuṣe ti o tọ si awọn aṣiṣe wa. Ko si ẹni ti o fi ipa mu u. O mọ ọ mọ gba iku si ori ara rẹ lati le san ohun ti idajọ n beere fun. Oun nikan ṣoṣo ni ẹni ti o gbe aye ri ti o si jẹ alailẹṣẹ, sibẹ o gba ki a ṣe si oun gẹgẹ bi a ti ṣe si aguntan inu itan Abdul-Rahman. Idi niyi ti o fi jẹ wipe, lẹyin ti o jiya fun wa, Ọlọrun gba a soke si ọrun.
Boya iwọ n jijadu ninu igbesi-aye e rẹ. Boya iwọ dabi i Fatima, tí ẹni tí o fẹ́ràn kọ̀ ọ́ silẹ. Boya ẹnikan ti pa ọ lara, tabi a ti ba ọ lorukọ jẹ ni ọna aitọ. Boya iwọ dabi Abdul-Rahman, ẹni ti o jẹbi ti o si n bẹru igbẹsan.
Jesu, Mesaya naa, le ṣe ìrànwọ́. Iwọ le gba adura kukuru bi iru eyi:
Oluwa, emi ko le san asanpada fun awọn ẹṣẹ mi. Ṣugbọn emi mọ pe Iwọ ran Jesu, Mesaya naa, si wa gẹgẹ bi Aanu Rẹ. Jọwọ dariji mi nitori iṣẹ rere ti o ti ṣe fun gbogbo eniyan. Ran mi lọwọ lati mọ nipa ọna Jesu, Mesaya naa, ki emi ba a le ni iriri aanu Rẹ ninu aye mi. Amin.
Bi iwọ ba fẹ ni ẹ̀dà Iwe Iyinrere yii funra rẹ, jọwọ kàn sí wa ni adirẹsi ti o wa ni ẹyin iwe yii.
Copyright © 2023 by Sharing Hope Publications. A le tẹ iwe yii jade ki a si pin kaakiri laifi ṣowo lai gba aṣẹ.A mu ẹsẹ Bibeli lati inu Bibeli Mimọ Alakọle. Copyright © 2012 lati ọwọ The Bible Society of Nigeria. A lo o pẹlu aṣẹ. A ni aṣẹ lori gbogbo iwe yii.
Fi orúkọ sílẹ̀ fun awọn ìwé-ìròyìn wa
Jẹ́ ẹni akọkọ ti yo o mọ igba ti awọn atẹjade tuntun bá ti jade!

Wá Àwọn Olugbọ ọ Rẹ
Awọn atẹjade ti o fi ara han
© 2024 Sharing Hope Publications