
Wíwà ni Àìbẹ̀rù ni Ìdájọ́
Akotan
Rironu nipa ọjọ idajọ ma a n fa ibẹru ninu ọkan ọpọlọpọ awọn eniyan. Bawo ni a ṣe le ni idaniloju pe ao ṣe aṣeyege ni ọjọ iṣiro ikẹyin? Ọlọrun sọ wi pe Oun yo o fun wa ni Alagbawi—Ẹni ti yo o bẹbẹ fun wa ni idajọ gẹgẹ bi agbẹjọro ti ṣe n gba ẹjọ wa ro ninu gbọngan idajọ aye. Iwe-ilewọ yi i fi Alagbawi na a han wa, o si kọ wa bi a ti ṣe le ni idaniloju bi a ti n ro nipa idajọ ti n bọwa.
Tẹ̀
Tract
Òǹtẹ̀wé
Sharing Hope Publications
A le è ri ní
19 Àwọn èdè
Àwọn Ojú-ewé
6
Ni owurọ ọjọ kan, mo kuro ni yara hotẹẹli mi lati lọ si ipade pataki kan. Mo ti pẹ, nitori naa mo n sare pẹlu ọkọ̀ mi—mo sare kọja gbedeke ti a faaye gba. Nigba ti mo de idaji ọna, ọga ọlọpa kan dami duro, o si sọ fun mi pe mo gbọdọ lọ si agọ ọlọpa! Ẹru ba mi, mo si di alailagbara nitori pe mo mọ pe mo jẹbi.
Lẹyin ti ọga ọlọpa naa ṣi faili lori ọrọ mi, o mu mi lọ si ile ẹjọ́ ti o wa ni ẹba ibẹ fun igbẹjọ. Mo pade ọrẹ mi kan ti o jẹ agbẹjọro nibẹ. O ya a lẹnu lati ri mi. Nigba ti mo ṣ’alaye ipo ti mo wa, o sọ pe, “Ma ṣ’aniyan. Emi maa ṣiṣẹ lori ọrọ rẹ.” Inu mi dun gan-an. Ọrẹ mi ni yoo jẹ agbẹjọro mi!
Nitori pe ọrẹ mi gba ẹjọ mi ro, owo itanran kekere ni adajọ naa ni ki n san. Mo kuro ni ile igbẹjọ naa, mo n yin Ọlọrun logo.
Nitootọ o jẹ ohun ti o banilẹru lati duro niwaju adajọ aye. Ṣugbọn ohun kekere ni bi a ba fi we diduro niwaju Ọlọrun ni Ọjọ Idajọ nla naa. Bi ọjọ naa ba de ni ọla, n jẹ iwọ yoo wa ni imura silẹ bi?
Mimura silẹ fun Idajọ
Awọn eniyan kan n fesi si idajọ ti n bọ pẹlu iwa aibikita. Wọn n mu ọti, wọn n mu siga, wọn n ta tẹ́tẹ́, wọn n lọ si ile igbafẹ oru, wọn n wo aworan ti ko dara. Wọn le mọ pe a n kọ awọn nnkan wọnyi silẹ sinu iwe akọsilẹ, ṣugbọn wọn ti ko si panpẹ itanjẹ Satani (ti a tun mọ si Shaytan). Wọn ko bikita.
Awọn miran fesi pẹlu ibẹru ti o pọ rekọja. Wọn ko gbọdọ da a laṣa lati pa adura kankan jẹ. Wọn n ro nipa ijiya iboji tabi ina ọrun apadi tobẹẹ gẹẹ ti wọn fi gbagbe ifẹ ati inu rere Ọlọrun.
Ṣugbọn gẹgẹ bi mo ti ni agbẹjọro ninu ile igbẹjọ, Ọlọrun fun wa ni alagbawi ti yoo ran wa lọwọ lati la idajọ kọja. Ko yẹ ki iwọ nikan da wa!
Tani Alagbawi Wa?
Ero nipa alagbawi kii ṣe ohun titun. Ni ọdọọdun, ọgọọrọ awọn arinrinajo ni wọn n ṣe ibẹwo si awọn ibi ijọsin ni North Africa, Middle East ati Asia. Ọpọ ni wọn n gbadura ni iboji awọn adari nla, ti wọn si gbagbọ pe wọn yoo bẹbẹ fun wọn.
O dara lati bọwọ fun awọn adari wọnyi, ṣugbọn gbigba adura si wọn tabi bibeere fun ẹbẹ wọn jẹ haramu patapata. Wọn ti ku, wọn ko si le ṣe ohun kan fun ọ. Ani awọn woli wa ninu iboji wọn, wọn n duro de Ọjọ Ajinde.
Bi o tilẹ jẹ pe haramu ni lati beere ki awọn oku o gbadura fun wa, ero nipa gbigbadura fun ẹlomiran jẹ ohun ti o tọna. Ṣugbọn ẹbẹ taani o jẹ itẹwọgba lọdọ Ọlọrun? O gbọdọ jẹ ti ẹni ti o
Wa laaye (nitori pe oku ko le sọrọ nitori wa).
Alailẹṣẹ (nitori ẹni ti ofin ba ti da lẹbi ko le ṣe alagbawi fun ẹlomiran).
Tani o ni awọn amuyẹ wọnyi? Ko si ẹlomiran bikoṣe Jesu Kristi olufẹ, ti a tun n pe ni Isa al-Masih, ẹni ti o wa laaye ni ọrun ti o si jẹ aláìlábàwọ́n.
Ronu nipa rẹ—n jẹ ẹlomiran wa ti o le sọ pe oun jẹ alailẹṣẹ? Adamu jẹ eso ti a ka leewọ; Noah (Nuhu) mu ọti amuyo; Abrahamu (Ibrahim) parọ; Mose (Musa) pa eniyan; Dafidi (Dawud) gba iyawo ọkunrin miran. Iwọ ko le ri woli kan ti ko ṣe aṣiṣe tabi ti ko beere fun idariji ri. Ṣugbọn Jesu Kristi ko dẹṣẹ ri. Oun funra rẹ sọ pe “Ẹni ti o ran mi si n bẹ pẹlu mi. . . . nitori ti Emi n ṣe awọn ohun ti o wu U ni igba gbogbo” (lati inu awọn Ihinrere, ti a tun mọ si Injeel, Johanu 8: 29).
Kikoju Idajọ Pẹlu Alaafia
Jesu Kristi wa laaye ni ọrun, o jẹ alailẹṣẹ patapata. O ṣetan lati jẹ alagbawi fun emi ati iwọ. O si n padabọ laipẹ.
Bi ó ba n padabọ lẹẹkeji, eyi tumọ si pe Jesu Kristi ni woli ti o kẹyin. Bẹẹni, o ju woli lọ—oun ni Alagbawi, Oluwa, ati Alaafia ni Ọjọ Idajọ. O sọ fun wa, “Lootọ lootọ . . . bi ẹnikẹni ba pa ọrọ mi mọ ki yoo ri iku lailai” (Awọn Iyinrere, Johanu 8:51).
Jesu ko ku; o wa laaye! O si n kó awujọ ara rẹ jọ lori ilẹ aye, ani nisinsinyii. Nigba miran o maa n pe awọn eniyan wa sinu awujọ yii nipa fifi ara han ninu ala gẹgẹ bi ọkunrin ti o wọ aṣọ funfun tabi nipa fifun wa ni iṣẹ-iyanu nigba ti a ba gbadura si Ọlọrun ni orukọ rẹ.
N jẹ iwọ fẹ ni alaafia ni Ọjọ Idajọ bi? Jẹwọ igbagbọ rẹ ninu Jesu Kristi. Ki lo de ti a yoo fi fi igbẹkẹle wa sinu awọn ti wọn ti ku ti wọn ko si mọ ohun ti yoo de ba wọn ni Ọjọ Idajọ? Jesu ni idaniloju nipa ààyè rẹ ni ọrun. Gẹgẹ bi ọrẹ mi agbẹjọro ninu ile igbẹjọ, yoo ran wa lọwọ.
Iwọ le maa ronu boya ohun ti o yanilẹnu bi eyi le jẹ otitọ. Jesu Kristi sọ wipe, “Bi ẹyin ba beere ohunkohun ni orukọ mi, emi yoo ṣe e” (Awọn Iyinrere, Johanu 14:14). Ṣe idanwo kan lati le ri daju boya otitọ ni ohun ti emi n sọ fun ọ. Bi Jesu ba ni agbara to bẹẹ lati koju awọn ipenija aye ni akoko yii, nitori naa a le gbẹkẹle lati jẹ alagbawi wa. Gbadura si Ọlọrun ni orukọ Jesu pẹlu ọkan otitọ ki o si ri ohun ti yoo ṣẹlẹ. Iwọ le gbadura:
Oluwa, emi fẹ lati mọ boya Jesu ni ẹni naa ti iwọ ti yan lati jẹ alagbawi wa ni idajọ. Bi o ba jẹ pe otitọ ni, jọwọ dahun adura mi fun (kọ ohun ti o ṣe alaini sibi). Emi beere fun eyi ni orukọ Jesu Kristi. Amin.
Bi iwọ yoo ba fẹ mọ si nipa bi a ti ṣe le tẹle Jesu Kristi, kan si wa ni adirẹsi ti o wa ni ẹyin iwe yii.
A mu ẹsẹ Bibeli lati inu Bibeli Mimọ Alakọle. Copyright © 2012 lati ọwọ The Bible Society of Nigeria. A lo o pẹlu aṣẹ. A ni aṣẹ lori gbogbo iwe yii.
Fi orúkọ sílẹ̀ fun awọn ìwé-ìròyìn wa
Jẹ́ ẹni akọkọ ti yo o mọ igba ti awọn atẹjade tuntun bá ti jade!

Wá Àwọn Olugbọ ọ Rẹ
Awọn atẹjade ti o fi ara han
© 2024 Sharing Hope Publications