
Aabo Kuro Lọwọ Awọn Ẹmi Aimọ
Akotan
Awọn ẹmi buburu lagbara, ṣugbọn wọn ko lagbara bi i Jesu Mesaya na a. Iwe-ilewọ yi i ṣe alaye bi Jesu ṣe lé awọn ẹmi aimọ jade kuro lara awọn eniyan ti n jiya ti O si ràn wọ́n lọwọ lati ri iwosan. Ó le ṣe ohun kan na a fun wa loni i. Iwe Rẹ̀ kọ́ wa ni ohun gbogbo ti a nilo lati mọ lati le ni ominira kuro lọwọ ifiyajẹni ati ipọnniloju awọn ẹmi aimọ. O tun kọ wa nipa bi a ṣe le yago fun itanjẹ awọn ẹmi aimọ ṣaaju ki O to pada de.
Tẹ̀
Tract
Òǹtẹ̀wé
Sharing Hope Publications
A le è ri ní
21 Àwọn èdè
Àwọn Ojú-ewé
6
Awọn anjọnu wa ni ibi gbogbo. Boya o pe wọn ni awọn ẹmi, esiku, ẹmi eṣu, tabi anjọnu, wọn le banilẹru. Awọn oniṣegun, babalawo, ati oogun wọpọ, ṣugbọn ṣe wọn le daabo bo wa nitootọ bi?
Emi yoo fẹ lati sọ fun ọ nipa awọn igbesẹ mẹta ti iwọ yoo fi ni aabo kuro lọwọ awọn ẹmi buburu ti o fi jẹ pe iwọ ki yoo fi bẹru mọ.
Ààbò Kuro Lọwọ Awọn Ẹmi Aimọ
Ọkunrin naa wa ni ihoho o si kigbe rara. Ọpọlọpọ awọn anjọnu ni wọn gbe e wọ̀, ko sì sí ẹnikan ti o le ran-an lọwọ. Awọn eniyan ti o wa ni abule naa ti gbiyanju lati de e pẹlu ẹwọn, ṣugbọn o ja wọn pẹlu agbara ti o ju ti eniyan lọ, o si salọ lati maa gbe ni aarin awọn iboji. O lo awọn akoko rẹ lati maa kigbe, o si n fi okuta ya ara rẹ.
Titi ti ọkunrin kan ti a n pe orukọ rẹ ni Jesu Kristi, ẹni ti a tun mọ si Isa al-Masih fi de.
Iya jẹ ọkunrin yii pupọpupọ ti o fi jẹ pe nigba ti o la ẹnu rẹ lati beere fun iranlọwọ, awọn anjọnu naa pariwo mọ Jesu Kristi ki o fi wọn silẹ. Ṣugbọn Jesu ko fi silẹ. O mọ ohun ti o n ṣẹlẹ. Laibẹru, o paṣẹ ki awọn anjọnu naa fi ọkunrin yii silẹ.
“Maṣe ran wa lọ sinu ọ̀gbun ainisalẹ!” awọn anjọnu naa bẹbẹ. Wọn bẹbẹ lati lọ sinu agbo awọn ẹlẹdẹ ti o wa nitosi. Jesu paṣẹ fun wọn ki wọn fi ọkunrin naa silẹ ki wọn si lọ sinu awọn ẹranko alaimọ naa. Lọgan ni iyè ọkunrin naa sọji, ti gbogbo agbo ẹlẹdẹ naa si fo kọja bebe okuta lọ sinu okun.
Nikẹyin, ọkunrin naa gba ominira. O kun fun ẹmi ọpẹ́! Ṣugbọn eyi kii ṣe opin itan naa. Jesu ni agbara nla lori awọn ẹmi aimọ. Nibikibi ti o ba lọ, o maa ń tú awọn eniyan ti anjọnu ba gbe wọ̀ silẹ. O tun fun awọn atẹle rẹ bakan naa ni aṣẹ lori eṣu:
Kiyesi i, Emi fun yin ni aṣẹ . . . lori i gbogbo agbara ọta, kò sì sí ohun kan bi o ti wu ki o ri, ti yoo pa yin lara. Ṣugbọn ki ẹ ma ṣe yọ si eyi, pe, awọn ẹmi n foribalẹ fun-un yin, ṣugbọn ẹ kuku yọ, nitori pe, a ti kọ orukọ yin ni ọrun (lati inu awọn iwe iyinrere, ti a tun mọ si Injeel, Luku 10:19, 20).
Nigba ti a ba tẹle Jesu Kristi, a le ni aabo ninu aye yii ati idaniloju fun aye ti n bọwa! Ẹ jẹki a wo awọn igbesẹ mẹta ti a fi le ni aabo kuro lọwọ awọn ẹmi aimọ.
Igbesẹ 1: Gba Agbara ti o wa Ninu Orukọ Jesu Kristi
Igbesẹ akọkọ ni lati wa aabo Ọlọrun ni orukọ Jesu Kristi. Ni ti ara wa, a jẹ alailagbara. Ṣugbọn nigba ti a ba pe orukọ Jesu Kristi sori igbesi aye wa, awọn ẹmi aimọ naa yoo di alailagbara! Jesu sọ niti awọn atẹle rẹ: “Ni orukọ mi ni wọn yoo le awọn ẹmi aimọ jade” (Awọn Iwe Iyinrere, Marku 16:17).
Bi iwọ ba gbagbọ pẹlu gbogbo ọkan rẹ pe Jesu Kristi yoo tu ọ silẹ, yoo ṣe e! Gba adura yii si Ọlọrun, “Oluwa, jọwọ gba mi kuro lọwọ awọn ẹmi aimọ ni orukọ ẹni ti Iwọ ran, Jesu Kristi!”
Igbesẹ 2: Wa Àfọ̀mọ́ Inu ati ti Ode
Jesu kọni pe a ko gbọdọ fi aaye kankan silẹ fun Eṣu. O wi pe, “Alaṣẹ aye yii wa, ko si ni ohun kan ninu Mi” (Awọn Iwe Iyinrere, Johanu 14:30). A gbọdọ fọ igbesi aye wa mọ kuro ninu agbara buburu gbogbo pẹlu.
Kini o tumọ si pe ẹmi aimọ ko ni “ohun kan ninu wa”? O tumọ si pe ko ni ohun kankan ninu ọkan tabi ninu ile wa ti o jẹ tirẹ. A gbọdọ ju awọn oogun ati ìgbàdí sọnù. A gbọdọ yago fun iwa ẹṣẹ bi wiwo aworan onihoho, oogun oloro, ati ọti. Bi a ba ti lọ́wọ́ ninu ilana biba oku sọrọ tabi ṣíṣẹ́ èpè, a gbọdọ dawọ awọn iwa wọnyi duro. Bayi ni a yoo ṣe fọ ayika ode wa mọ kuro ninu ipa awọn ẹmi aimọ. Lẹyin naa, a gbọdọ gbadura si Ọlọrun ki o dariji wa, ki o si fọ wa mọ ninu.
Igbesẹ 3: Fi Imọlẹ Kún Igbesi-Aye Rẹ
Lẹyin ti Kristi ba gba ọ silẹ kuro lọwọ agbara ẹmi aimọ tan, pe e lati jẹ alakoso aye rẹ. Maṣe jẹki ọkan rẹ o wa ni ofifo. Jesu Kristi sọ pe,
Nigbati ẹmi aimọ kan ba jade kuro lara eniyan, a maa rin kiri ni awọn ibi gbigbẹ, a maa wa ibi isinmi, ki yoo si ri. Nigba naa ni o wi pe, “Emi yoo pada lọ si ile mi, nibi ti emi ti jade wa.” Nigba ti o si de, o baa, lofifo, a gbá a mọ́, a si ṣe e lọṣọ. Nigba naa ni o lọ, o si mu ẹmi meje miran pẹlu rẹ, ti o buru ju oun tikara rẹ lọ, wọn si bọ si inu rẹ, wọn si n gbe ibẹ; igbẹyin ọkunrin naa si buru ju ti iṣaaju lọ (Awọn Iwe Iyinrere, Mattiu 12:43–45).
Nigba ti a ba fọ̀ ọ́ mọ kuro lọwọ awọn anjọnu tan, jẹ ki imọlẹ Bibeli, iwe Jesu, o kun igbesi aye rẹ. Jesu wa gẹgẹ bi “imọlẹ sinu aye, ki ẹnikẹni ti o ba gba [a] gbọ ki o maṣe wa ninu okunkun” (Awọn Iwe Iyinrere, Johanu 12:46). Gba ẹ̀dà iwe Jesu ki o si maa ka a lojoojumọ ki imọlẹ Rẹ ba a le lé okunkun jade.
Aabo fun Ọjọ Iwaju
A n sunmọ akoko ikẹyin nigba ti awọn ẹmi aimọ n ṣiṣẹ karakara ju ti atẹyinwa lọ. Jesu Kristi sọ tẹlẹ pe ki oun o to pada de, awọn agbara ẹmi aimọ yoo ṣe ọpọlọpọ iṣẹ iyanu eke lati gbiyanju lati tan awọn onigbagbọ jẹ. Si awọn miran, awọn anjọnu yoo farahan ni ọna ti o banilẹru bi iwin; si awọn miran, wọn yoo farahan bi awọn angẹli tabi ara-ile ti o ti ku. Ani Eṣu funra rẹ yoo fi ara rẹ han gẹgẹ bii Jesu Kristi!
Ṣugbọn a ko nilo lati tan ọ jẹ pẹlu irọ. Bi iwọ ba tẹle Jesu Kristi, yoo fun ọ ni agbara lati koju ija si Eṣu. Iwọ ọrẹ, ohun yoo wu ki o jẹ ijijadu rẹ loni, jẹki Jesu Kristi sọ ọ di ominira!
Bi iwọ yoo ba fẹ ki atẹle Jesu Kristi kan o gbadura itusilẹ fun ọ kuro lọwọ awọn emi aimọ, jọwọ kan si wa nibi adirẹsi ti o wa ni ẹyin iwe yii.
Copyright © 2023 by Sharing Hope Publications. A le tẹ iwe yii jade ki a si pin kaakiri laifi ṣowo lai gba aṣẹ.A mu ẹsẹ Bibeli lati inu Bibeli Mimọ Alakọle. Copyright © 2012 lati ọwọ The Bible Society of Nigeria. A lo o pẹlu aṣẹ. A ni aṣẹ lori gbogbo iwe yii.
Fi orúkọ sílẹ̀ fun awọn ìwé-ìròyìn wa
Jẹ́ ẹni akọkọ ti yo o mọ igba ti awọn atẹjade tuntun bá ti jade!

Wá Àwọn Olugbọ ọ Rẹ
Awọn atẹjade ti o fi ara han
© 2024 Sharing Hope Publications