Ipe lati ṣilọ si Ilu Miiran!

Ipe lati ṣilọ si Ilu Miiran!

Akotan

N jẹ iwọ n wọna fun ibi ti o dara bi? Ibi aabo, idunnu ati isinmi? A n wọna fun ohun ti aye yi i ko le fun wa nitori pe a da olukuluku wa fun Paradise. Jesu, Mesaya ti kọkọ lọ sibẹ na. O mọ ọna na a, ani, O pe ara Rẹ ni "ọna na a!" Iwe ilewọ yi i ṣe alaye awọn otitọ pataki nipa Jesu ti wọn le ran wa lọwọ lati mura silẹ lati jẹ ọmọ ilu ni Paradise.

Tẹ̀

Tract

Òǹtẹ̀wé

Sharing Hope Publications

A le è ri ní

21 Àwọn èdè

Àwọn Ojú-ewé

6

Danloodu

Abdul-Malek jẹ agbalagba ti o jẹ alailagbara. Lẹyin ti o padanu iyawo ati awọn ọmọ rẹ tan, o sa kuro ni Iraq lati sa asala kuro ni ISIS. Bayii o n gbe ni Jordan ni oun nikan gẹgẹ bi atipo.

Ṣugbọn òjijì ìrètí wá. O ni ibatan kan ti n gbe ni Canada ti o fẹ lati ran-an lọwọ lati ri iṣẹ. Inu rẹ dun, o beere fun iwe iwọlu o si bẹrẹ si ni lala nipa igbe aye irọrun. Nikẹyin, lẹyin ti o ti duro fun ọpọ ọdun, a fun ni anfani lati wọ Canada. Inu Abdul-Malek dun!

Ṣugbọn ayọ rẹ ko tọ́jọ́. Lẹyin ti o de Canada, o ri pe aye ko rọrun lẹyin ti a ba ko lọ si ilu miiran. Iṣẹ rẹ mu ki o wa lori iduro ni gbogbo igba. Awọn aladugbo rẹ jẹ alariwo. Ko rọrun lati ni imọ nipa eto ìwọkọ̀ laarin ilu -- bẹẹ ni ede Gẹẹsi pẹlu kò dán mọ́rán! 

Abdul-Malek ti ma a n ronu lati lọ si ibi ti o dara ju ibi ti o wa tẹlẹ lọ, ṣugbọn nigba ti o debẹ, o ri pe oun ṣi ni ibanujẹ ọkan. O bẹrẹ si ni ronu boya ibi kan wa ti o ti le ni itẹlọrun ni ori ilẹ aye—tabi boya yoo nilo lati duro de Paradise funra rẹ!

Lilọ si Paradise

N jẹ iwọ ti ni iru imọlara Abdul-Malek yii ri? Ifẹ lati lọ si ibi ti o dara julọ si wa ni ọkan eniyan, wiwọ inu Paradise, ile wa tootọ, nikan si ni o le tẹ imọlara yii lọrun. O jẹ ifẹ-ọkan ti yoo wa si imuṣẹ laipẹ! Awọn Ami Akoko naa n ṣẹlẹ niwaju wa, aye yii si n yara lọ si opin.

Fun ọpọlọpọ ọdun, awọn iwe ẹsin awọn Ju, ti awọn Kristẹni, ati ti awọn Musulumi ti sọtẹlẹ nipa iṣẹlẹ ikẹyin—iṣẹlẹ aṣekagba nigba ti a yoo “kuro” ninu aye yii lọ si aye miran. Awọn igbagbọ mẹtẹẹta ni wọn tọka si ẹnikan ti o dabi Mesaya ti yoo mu awọn iṣẹlẹ ikẹyin wọnyi ṣẹ.    

O dun mọni pe ẹni ti o dabi Mesaya yii ninu ẹsin Kristẹni ati Islam kii ṣe ẹlomiran bikoṣe Jesu Kristi, ẹni ti a tun mọ si Isa al-Masih. Oun ni Mesaya nigba ti o gbe ni Palẹstini, ṣugbọn lati nkan bi i ẹgbẹrun ọdun meji sẹyin ni o ti n gbe ni Paradise. Yoo pada wa nikẹyin ni Ọjọ Idajọ. 

Ipadabọ Jesu Kristi ni a mẹnuba daradara ninu Bibeli, ṣugbọn awọn Musulumi gbagbọ pe o n padabọ pẹlu, niwọn igba ti a ti kọ sinu Kurani: “Dájúdájú òun (Jesu Kristi) ni ìmọ̀ (tàbí àmì fún ìsúnmọ́) Àkókò náà (Wakati Idajọ). Nítorí náà, ẹ kò gbọdọ̀ ṣeyèméjì lórí rẹ̀. Kí ẹ sì tẹ̀lé mi. Èyí ni ọ̀nà tààrà” (As-Sukhruf 43: 61).

Gẹgẹ bi oṣiṣẹ ni ile iṣẹ ti n moju to irin-ajo lọ si ilu miran ti o n lani lọyẹ nipa bi a ti ṣe le gba iwe-ìrìnnà, Jesu n pe wa lati fiyesi Ami Rẹ ki a ba a le mọ Ọna Taara ti o lọ si Paradise. 

Bawo ni Jesu ṣe Ṣalaye Paradise?

Awọn Iyinrere, ti a tun mọ si Injeel, ṣe akọsilẹ wipe Jesu Kristi wipe, “Emi n lọ pese aye silẹ fun yin. Bi emi ba si lọ pese aye silẹ fun yin, emi yoo si tun pada wa, emi yoo si mu yin lọ si ọdọ emi tikara mi; pe nibi ti emi ba gbe wa, ki ẹyin le wa nibẹ pẹlu” (Iyinrere, Johanu 14:2, 3). Jesu Kristi sọ wipe oun le mu wa lọ si Paradise! 

O tun ṣe afihan awọn aworan ti o rẹwa nipa ibẹ. O wi pe

  • Ki yoo si sí iku mọ, tabi ọ̀fọ̀ tabi ẹkún, bẹẹni ki yoo si irora mọ (Ifihan 21:4).

  • A yoo ni ile ti o rẹwa (Johanu 14:2).

  • Awọn ọkunrin ati awọn obinrin yoo ni iyì ati ẹ̀tọ́ kan naa (Galatia 3:28).

  • O kun fun imọlẹ, òdodo, ati idunnu (Ifihan 21:21–25).

Nitootọ, o jẹ ibi ti ọkan wa nifẹ si!  

Kini Idi ti Jesu Kristi yoo fi wá ni Ẹẹkeji

Ṣugbọn Ọlọrun ti ran ọpọ awọn woli ati awọn iranṣẹ mimọ wa. Kini idi ti a fi yan Jesu Kristi lati pada wa ni ẹẹkeji? O rọrun lati dahun ibeere yii pẹlu iru akawe irin-ajo kan naa lọ si orilẹ-ede miiran. Nitori pe ko rọrun lati gba iwe-irinna, ọpọlọpọ awọn eniyan ni wọn gba agbẹjọro ti o mọ ofin nipa lilọ si ilu miran, ẹni ti o mọ ọna. Bi a ba ni amọna, a le gbẹkẹle e lati ran wa lọwọ.

Ni ọna kan naa, Jesu Kristi ni ẹni kan ṣoṣo ti o farahan ni ẹẹkeji nitori pe o mọ ọna ti o lọ si Paradise, o si le dari wa lọ sibẹ. Oun funra rẹ sọ pe, “Emi ni ọna, otitọ ati iye” (Johanu 14:6).

Gbogbo awọn woli ati awọn iranṣẹ ti Ọlọrun ran ni wọn ti ṣe awọn aṣiṣe ti wọn si nilo lati bẹbẹ fun idariji. Ṣugbọn ko ri bẹẹ fun Jesu Kristi. O jẹ alailẹṣẹ fun ọdun mẹtalelọgbọn ti o lo lori ilẹ aye. Idi niyi ti a fi mu lọ si Paradise lọgan.

A gbọdọ kẹkọ lọdọ Jesu Kristi, ẹni ti o jẹ alailẹṣẹ naa, nipa bi a ti ṣe le kun oju oṣuwọn lati wọ Paradise. Ni ọna yii nikan ṣoṣo ni a fi le ri aaye wọle. A dupẹ pe a le kẹkọ lati inu iwe rẹ, Bibeli. 

Mimura silẹ Fun Ipadapọ Jesu Kristi

Ṣe ko yanilẹnu pe iwọ le ni idaniloju nipa bi o ti ṣe le lọ si ibi ti o dara ju ibi ti o wa tẹlẹ lọ? A pe ọ lati jẹ ọmọ ijọba ologo Ọlọrun ninu Paradise! Laipẹ Jesu Kristi yoo wa lati mu gbogbo wa lọ si ibi ti o dara naa.

N jẹ o ṣe e ṣe pe iwọ n tẹle awọn eniyan ti awọn funra wọn ko mọ ohun ti yoo ṣẹlẹ si wọn ni Ọjọ Idajọ?  Pẹlu Jesu Kristi, iwọ ko nilo lati ṣiyemeji. Beere lọwọ Ọlọrun lati dari rẹ ni Ọna Taara ti Jesu Kristi. Iwọ le gba iru adura yii:

Oluwa, ọkan mi n wọna fun ibi ti o dara ju ibi ti a wa yii lọ. Jọwọ gba emi ati awọn ololufẹ mi kuro ninu awọn inira aye yii. Emi gbagbọ pe akoko naa kuru. Jọwọ fun mi ni itọni ki emi ba a le wọ ibi iyanu ti iwọ ti pese silẹ fun mi. Amin.

Bi iwọ ba fẹ lati ni ẹda iwe Iyinrere ti o jẹ ojulowo, jọwọ kan si wa ni adirẹsi ti o wa ni ẹyin iwe yii.

Itumọ Kurani Alápọ́nlá ni Ede Yoruba.Copyright © 2023 by Sharing Hope Publications. A le tẹ iwe yii jade ki a si pin kaakiri laifi ṣowo lai gba aṣẹ.
A mu ẹsẹ Bibeli lati inu Bibeli Mimọ Alakọle. Copyright © 2012 lati ọwọ The Bible Society of Nigeria. A lo o pẹlu aṣẹ. A ni aṣẹ lori gbogbo iwe yii.

Fi orúkọ sílẹ̀ fun awọn ìwé-ìròyìn wa

Jẹ́ ẹni akọkọ ti yo o mọ igba ti awọn atẹjade tuntun bá ti jade!

newsletter-cover